Lagos Island
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìsàlẹ̀ Èkó (Lagos Island)[1] jẹ́ àárín gbùngbùn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ , ìpínlẹ Èkó. Ó jẹ́ ọ̀kan lára ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n pín ìpínlẹ̀ Èkó sí. [2] Nínú ètò ìkànìyàn tó wáyé ní ọdún 2006 nílẹ̀ Nàìjíríà, ìjọba ìbílẹ̀ náà ni ìwọ̀n èrò tó pọ̀ tó 209,437 ní agbègbè tí kò ju ìwọ̀n ibùsọ̀ 8.7 km² [3]. Ìjọba ìbílẹ̀ Ìsàlẹ̀ Èkó ló kó ìlàjì nínú apá ìwò Oòrùn Lagos Island, nígbà tí apá ìlà Oòrùn Ìsàlẹ̀ Èkó tókù wà ní abẹ́ àkóso ìjọba ìbílẹ̀ Etí-Ọ̀sà.