From Wikipedia, the free encyclopedia
Àdàkọ:CaInfoboxpe Verde settlement Cidade Velha (Portuguese city atijọ́", tabí: Santiago de Cabo Verde) jẹ́ ìlú kan [1] tí ó wà ní apá ìlà Oòrùn erékùṣù Santiago, Cape Verde. Wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1462,[2]:77 òun ni ó jẹ́ ìlú tí ó pẹ́ jùlọ ní agbégbè Cape Verde tí ojẹ́ olú ìlú ibé tẹ́lẹ̀. Wọ́n ti fìgbà kan rí pèé ní Ribeira Grande, wọ́n sì yi padà síCidade Velha ní àsìkò sẹ́ntírì kejìdínlógún (18th century).[3] Òun ni ó jẹ́ olú ìlú fún Ribeira Grande de Santiago. Ìlú yí wà ní agbègbè aríwá ilẹ̀ Áfíríkà, ó sì tún jẹ́ ibi tí awọ èèbó àmúnisìn ará Yúróòpù gúnwà sí. Púpọ̀ nínú awọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ṣe sí ìlú yí ni ó ṣì wà níbẹ̀ digbí, tí ó fi mọ́ ilé-ìjọsìn ati ọjà tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 16th sẹntirì ní wọ́n ṣì wà títí dòní. Lóní, Cidade Velha ni ó jẹ́ arin gbùngbù ọjà ìkẹ́rù wọ̀ ati ojú àṣà Creole. Àjọ UNESCO sọ ìlú yí di World Heritage Site àti ìkan lára Seven Wonders of Portuguese Origin in the World ní ọdún 2009.[3]
Cidade Belha wà ní apá ìlà Oòrun erékùṣù Santiago, lẹ́nu odò Cidade Velha Ribeira Grande de Santiago.Ó tó kìlómítà mẹ́wá sí olú-ìlú , àwọn ìlú tí wọ́n jẹ́ alámúlégbè Cidade ni: Largo Pelourinho, São Sebastião, Santo António and São Pedro.
António da Noli,ni ó ṣàwárí ìlú t tí ó di Cidade Velha lóní ní nkan bí ọdún 1460.[2]:73 Da Noli kọ́kọ́ fìdí kalẹ̀ sí agbègbè Ribeira Grande pẹ̀lú àwọ ẹbí rẹ̀ láti orílẹ̀-èdè Potogí àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti Algarve àti Alentejo ní ọdun 1462. .[2]:77 Ojú ọjọ́ ilẹ̀ náà bá wọn lára mu, pàá pàá jùlọ omi tí ó ń ṣàn láti dò Rebeira Grande tíjẹ́ kí ó ní ànfàní ju àwọn ìlú bíi: Alcatrazes.[2]:80 Ìletò yí wá di ojúkò fún àwọn Potogí láti ṣe òwò-ẹrú ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ati ati Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ní àsìkò ọ̀rùndún kẹrìndínlógún sí ìkẹtàdínlógún Cidade Valhe jẹ́ gbajúbajà ojúkò okòwò fún àwọn arì rìn-àjò ojú omi láàrín ilẹ̀ Áfíríkà àti Cape, Brazil àti Caribbean.Látàrí bí ilẹ̀ yí ó ti ṣe fẹ̀ tó ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ó ṣe jẹ́ kí ó di ojúkò fún òwò ẹrú ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.[3] Cidade Velha jẹ́ ibi tí àwọn arìnrìn-àjò oníwádí bí Vasco da Gama,ní nkan bí ọrún 1497 nígbà tí ó ń lọ sí ilẹ̀ India . Bákan náà ni Christopher Columbus tí ó ń lọ sí Amẹ́ríkà fún ẹlẹ́kẹta orúfẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1498. Bákan náà ni Ferdinand Magellan tí ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ orílẹ̀-èdè Spain. Ilú Cidade Velha ni ó ní ilé-ìjọsìn ọmọ lẹ́yìp Jésù tí ó dagbà jùlọ lágbàáyé , orúkọ ilé ìjọsìn náà ni Nossa Senhora do Rosário church,tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1495. Cidade Velha di ilé àṣẹ fún fún àwọn Roman Catholic Diocese of Santiago de Cabo Verde,èyí tí póòpù tẹ́lẹ̀ rí Pope Clement VII. Ìdàrúdàpọ̀ tí ó wáyé láàrín Ribeira Grande ati àwọn àmúnisìn Pọ́túgà ti ilẹ̀ Faramsé ati ilẹ̀ Brítènì ni ó mú kí àwọn agbésùnmọ̀mí orí omi bíi: Francis Drake (1585) àti Jacques Cassard (1712).[2]:195 Pẹ̀lú akitiyan bí wọ́n ṣe kọ́ Forte Real de São Filipe ní ọdún 1587–93, síbẹ̀ Ribeira Grande kò fi bẹ́ẹ̀ ní ààbò tó péye. Wọ́n gbé olú-ìlú rẹ̀ lọ sí Praia ní ọdún 1770 .[4]
Ribeira Grande tí ó ti di (Cidade Velha)ni ó ti di abúlé nísìnyí látàrí wípé kò sí ilé ikọ̀ awọn ọmọ ológun àti ilé ìjọsìn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni wọ́n ti di àlòpatì . Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe ní ati ọdún 1960, restoration .[5]:70 Ó di UNESCO' World Heritage Site ní ọdún 1990.[3]
Iye olugbe ilu Cidade Velha ni odun (1990–2010) | |
---|---|
1990[citation needed] | 2010[6] |
2148 | 1214 |
Cidade Velha ni o ni awon asale bii: hot arid climate (Köppen BWh). Iye ojo ti o ma n ro nibe ni 201 millimetres or 7.91 inches, iye oorun ti o ma n mu nibe ni 25.2 °C or 77.4 °F. Bákan náà, ní inú oṣù kínní ọdún ni òtútù ma ń mú jùlọ ní déédé 23.0 °C or 73.4 °F nígbà tí oru ma ń pọ̀ jùlọ nínú oṣù kẹwá ọdún ní déédé 28.0 °C or 82.4 °F.[7]
Dátà ojúọjọ́ fún Cidade Velha, 1 metre ASL | |||||||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
Osù | Jan | Feb | Mar | Apr | May | Jun | Jul | Aug | Sep | Oct | Nov | Dec | Ọdún |
Iye àmúpín tógajùlọ °C (°F) | 26.7 (80.1) |
27.2 (81) |
27.9 (82.2) |
28.3 (82.9) |
28.5 (83.3) |
29.6 (85.3) |
29.4 (84.9) |
30 (86) |
30.6 (87.1) |
31 (88) |
29.7 (85.5) |
27.3 (81.1) |
28.85 (83.95) |
Iye àmúpín tókéréjùlọ °C (°F) | 19.4 (66.9) |
19.2 (66.6) |
19.7 (67.5) |
20.1 (68.2) |
21 (70) |
21.8 (71.2) |
22.5 (72.5) |
23.7 (74.7) |
23.9 (75) |
25 (77) |
22.3 (72.1) |
20.8 (69.4) |
21.62 (70.93) |
Iye àmúpín ìrọ̀jò mm (inches) | 2 (0.08) |
2 (0.08) |
0 (0) |
0 (0) |
0 (0) |
0 (0) |
7 (0.28) |
50 (1.97) |
90 (3.54) |
40 (1.57) |
9 (0.35) |
1 (0.04) |
201 (7.91) |
Source: climate-data.org[7] |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.