![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/0/05/Flag_of_Brazil.svg/langyo-640px-Flag_of_Brazil.svg.png&w=640&q=50)
Brasil
From Wikipedia, the free encyclopedia
Brasil /bɹəˈzɪl/ (Pọrtugí: Brasil, IPA: [bɾaˈziw][8]), lóníbiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira Aparapọ̀ ilẹ̀ Bràsíl (Federative Republic of Brazil[9][10] (Pọrtugí: República Federativa do Brasil, listen (ìrànwọ́·ìkéde)), ni orílẹ̀-èdè tótóbijùlọ ní Gúúsì Amẹ́ríkà àti ní agbègbè Amẹ́ríkà Látìnì. Òkòwò rẹ̀ ni ìkaàrún tótóbijùlọ lagbaye, gegebi àlà jeografi àti bii alabugbe pelu 193 million eniyan.[11][3] Brasil ni orile-ede Eledeluso totobijulo lagbaye, ati ikan soso ni orile awon Amerika.[11]
Àyọkà yìí únfẹ́ ìyílédèdà sí Yorùbá. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ ṣàtúnṣe sí ìyílédèdà |
Orílẹ̀-èdè Olómìnira Aparapọ̀ ilẹ̀ Bràsíl Federative Republic of Brazil República Federativa do Brasil (Pọrtugí)
| |
---|---|
![]() | |
Olùìlú | Brasília |
Ìlú tótóbijùlọ | São Paulo |
Àwọn èdè ìṣẹ́ọba | Pọrtugí[1] |
Àwọn ẹ̀yà ènìyàn (2010[2]) | 47.73% Aláwọ̀funfun 43.13% Brown (Ẹlẹ́yàpúpọ̀) 7.61% Adúláwọ̀ 1.09% Asian 0.43% Amerindian |
Orúkọ aráàlú | Brazilian |
Ìjọba | Orílẹ̀-èdè olómìnira oníàrẹ àpapọ̀ |
• Ààrẹ | Luiz Inácio Lula da Silva |
• Igbákejì Ààrẹ | Geraldo Alckmin |
• Ààrẹ ilé Aṣòfin | Arthur Lira |
• Ààrẹ ilé Alàgbà | Rodrigo Pacheco |
• Ààrẹ Ilé-ẹjọ́ Gígajùlọ | Luiz Fux |
Aṣòfin | Kọ́ngrésì Orílẹ̀-èdè Brasil |
• Ilé Aṣòfin Àgbà | Ilé Alàgbà Àpapọ̀ |
• Ilé Aṣòfin Kéreré | Ilé àwọn Aṣofin |
Ilómínira látọ̀dọ̀ United Kingdom of Portugal, Brazil and the Algarves | |
• Filọ́lẹ̀ | 7 September 1822 |
• Recognized | 29 August 1825 |
• Orílẹ̀-èdè olómìnira | 15 November 1889 |
• Current constitution | 5 October 1988 |
Ìtóbi | |
• Total | 8,514,877 km2 (3,287,612 sq mi) (5th) |
• Omi (%) | 0.65 |
Alábùgbé | |
• 2012[3] estimate | 193,946,886 |
• 2010 census | 190,732,694[4] (5th) |
• Ìdìmọ́ra | 22/km2 (57.0/sq mi) (182nd) |
GDP (PPP) | 2011 estimate |
• Total | $2.294 trillion[5] (7th) |
• Per capita | $11,769[5] (75th) |
GDP (nominal) | 2011 estimate |
• Total | $2.493 trillion[5] (6th) |
• Per capita | $12,788[5] (53rd) |
Gini (2012) | ▼51.9[6] Error: Invalid Gini value |
HDI (2011) | 0.718[7] Error: Invalid HDI value · 84th |
Owóníná | Real (R$) (BRL) |
Ibi àkókò | UTC−2 to −4 (BRT) |
• Ìgbà oru (DST) | UTC−2 to −4 (BRST) |
Irú ọjọ́ọdún | dd/mm/yyyy (CE) |
Ojúọ̀nà ọkọ́ | right |
Àmì tẹlifóònù | +55 |
ISO 3166 code | BR |
Internet TLD | .br |
O ni bode mo Okun Atlantiki ni ilaorun, Brasil ni etiomi to to 7,491 km (4,655 mi).[11] O ni bode ni ariwa pelu Venezuela, Guyana, Suriname ati agbegbe okere Fransi ni Guiana fransi; ni ariwaiwoorun pelu Kolombia; ni iwoorun pelu Bolivia ati Peru; ni guusuiwoorun pelu Argentina ati Paraguay ati ni guusu pelu Uruguay. Opo awon erekusu osupo wa ni ara ile Brasil, bi Fernando de Noronha, Rocas Atoll, Saint Peter and Paul Rocks, ati Trindade and Martim Vaz.[11] O ni bode mo gbogbo awon orile-ede Guusu Amerika ayafi Ekuador ati Tsile.
Brasil tele je imusin Portugal latigba ti Pedro Álvares Cabral gunle sibe ni 1500 titi di 1815, nigba to di ileoba ati Ileoba Asokan Portugal, Brasil ati awon Algafe je didasile. Ibase amusin na je gige ni 1808, nigbati oluilu ileobaluaye alamusin Portugal je gbigbe kuro ni Lisbon lo si Rio de Janeiro, leyin igba ti Napoleon gbogunlu Portugal.[12] Brasil gba ilominira ni 1822 pelu idasile Ileobaluaye ile Brasil, orile-ede abasokan pelu iru ijoba kabiyesi onilanairepo ati sistemu onileasofin. Brasil orile-ede olominira oniare ni 1889, nigba ti ifipagbajoba ologun sakede Orile-ede Olominira, botilejepe ileasofin oniyewu meji, loni to n je Kongresi, ti wa lati igba itowobowe ilanairepo akoko ni 1824.[12] Ilanairepo Brasil loni, to je dida ni 1988, pe Brasil ni Orile-ede Olominira Apapo.[13] Iparapo orile-ede na waye pelu isokan larin Agbegbe Ijoba Apapo, awon Ipinle 26, ati awon Agbegbe ibile 5,564.[13][14]
Okowo Brasil ni ikefa totobijulo lagbaye gegebi GDP oloruko ati ikeje totobijulo gegebi osuwon agbara inawo (titi de 2011).[15][16] Brazil ni ikan ninu awon okowo gbangba to unsare dagba julo lagbaye. Awon atunse okowo to waye ti fun ni idamo tuntun kariaye.[17] Brasil je omoegbe oludasile Awon Orile-ede Asokan, G20, CPLP, Isokan Latini, Agbajo awon Orile-ede Iberia Amerika, Agbajo awon Orile-ede Amerika, Mercosul ati Isokan awon Orile-ede Guusu Amerika, ati ikan ninu awon orile-ede BRIC. Bakana Brasil tun je ikan ninu awon awon orile-ede Olohun-orisirisi 17, ibe je ile fun awon orisi eran igbe, ayika adanida, opo awon alumoni adanida nibi orisi ibi abo.[11] Pelu awon eya 67 abinibi ti won da duro, Brasil ni iye awon eniyan aitibapade to pojulo lagbaye.[18]