Àwọn Amino acid
From Wikipedia, the free encyclopedia
Àwọn amino acid jẹ́ àwọn ohun tí ó ní carbon tí ó wúlò fún ara tí ó sì ní amine (-NH2) àti carboxylic acid (-COOH) gẹ́gẹ́ bíi àwọn akójọpọ̀ fún iṣẹ́ ṣiṣe, tí ó sábà maa ń ní ìsomọ́ lẹ́gbẹ́ pàtó fún amino acid kọ̀ọ̀kan.[1][2][3] Àwọn ìdá ìpilẹ̀ amino acid tó ṣe kókọ́ ni carbon, hydrogen, oxygen, àti nitrogen, bípótilẹ̀jẹ́wípé a maa ń rí àwọn ìdá ìpilẹ̀ tókù nínú àwọn ìsomọ́ lẹ́gbẹ́ àwọn amino acid kọ̀ọ̀kan. Àwọn amino acid tí a mọ̀ fẹ́ẹ tó bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tí a sì lè pín sí ìsọ̀rí lóríṣiríṣi ọ̀nà.[4] A lè pín wọn gẹ́gẹ́ bi ìrísi àti àyè tí àwọn ẹgbẹ́ oníṣé wọn wà, bíi alpha- (α-), beta- (β-), gamma- (γ-) or delta- (δ-) amino acid; àwọn ẹ̀ka tókù ní lati ṣe pẹ̀lú òpó, ìwọn pH àti oníṣé irú ìsomọ́ ẹ́gbẹ́ (aliphatic, acyclic, aromatic, tí ó ní hydroxyl àti sulfur, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.). Ní bíi protein amino acid jẹ́ ẹ̀yà kejì tí ó tóbi jùlọ nínú iṣan (omi ni o poju) ninu isan, sẹ́ẹ̀lì àti tíṣ́ù.[5] Tí kò bá sí ní protein, ó maa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì bíi nuerotransmitter àti ìṣẹ̀dá ní ara.
Ní biochemistry, àwọn amino acid tí ó ní amine àti àkójọpọ̀ carboxylic acid so mọ́ carbon átọ́mù àkọ́kọ́ (alpha-) ń ní iṣẹ̀ pàtàkì kan pàtó. A mọ̀ wọ́n sí 2-, alpha-, tàbí α-amino acids (àgbékalè wọn maa ní H2NCHRCOOH,[6] R jẹ́ àwọn ohun tí ó ní carbon tí ó dìrọ̀ mọ́ọ tí a mọ̀ sí "ìsomọ́-ẹ̀gbẹ́");[7] a sì maa sábà pè wọ́n ní "amino acid". Mẹ́tàlélógún ni àwọn proteinogenic ("ìṣẹ̀dá-protein") amino acid náà [8][9][10] tí wọ́n maa ń sopọ̀ mọ́ peptide ("polypeptides") lati ṣètò ìpilẹ̀ fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ protein. [11] Gbogbo àwọn wònyí ni L-stereoisomers (isomer "lápá-òsì"), bótilèjépé awon D-amino acid ("alapa-otun") díẹ̀ wà nínú ẹ̀yà ìdáàbòbò ara bacteria, wọ́n lè jẹ́ neuromodulator (D-serine), wón tún wà nínú àwọn egbògi kànkàn.[12] Ogún nínú àwọn proteinogenic amino acid naa ní ó ń kóòdù tààrà nípasè kóòdù onímẹta nínú kóòdù jiini a si mo won si "standard" amino acid.