![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/6/60/Yam_pottage.jpg/640px-Yam_pottage.jpg&w=640&q=50)
Àsáró
From Wikipedia, the free encyclopedia
Àsáró jẹ́ orúkọ àpapọ̀ fún irúfẹ́ oúnjẹ tí a sè pẹ̀lú àwọn èròjà oríṣiríṣi sè papọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Oríṣiríṣi àsáró lò wà nílẹ̀ Yorùbá, àsáró iṣu, àsáró[1]ànàmọ́, àsáró kókò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[2]Èyíkéyìí nínú àsáró tí wọ́n bá sè ni wọ́n máa ń kó ohun èròjà onírúurú papọ̀ láti fi pèsè oúnjẹ aládìídùn yìí. Àsáró jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ Adúláwọ̀ pàá pàá jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà máa ń jẹ sùn lálẹ́ tàbí ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ọ̀sán tàbí bí ìpanu lásán ṣáájú oúnjẹ gidi.[3]
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/6/60/Yam_pottage.jpg/640px-Yam_pottage.jpg)