From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìjọba Zulu ( /ˈzuːluː/), tí àwọn mìíràn mọ̀ sí Ìjọba Zululand, tí ó jẹ́ ìjọba kan ní Apá gúúsù Áfríkà. Nígbà àwọn ọdún 1810s, Shaka dá ọmọ ogun tí ó padà darapọ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ogun ìran míràn láti darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ní Apá Gúúsù Áfríkà kọjá apá kan etí Òkun Índíà láti Odò Tugela ní gúúsù dé Pongola River ní àríwá.
|
Ogun abẹ́lé kan ṣẹ̀lẹ̀ ní àárín ṣẹ́ńtúrì ọ̀kàndínlógún, ogun yìí padà yọrí sí ogun Ogun Ndondakusuka láàrin àwọn arákùnrin Cetshwayo àti Mbuyazi ní 1859. Ní ọdún 1879, àwọn ológun Britain kógun wo Zululand, èyí ni ó yọrí Ogun Anglo-Zulu. Lẹ́yìn ìṣègùn àkọ́kọ́ tí Zulu ní Ìṣẹ́gun Isandlwana ní oṣù kínní, àwọn ọmọ ogun Britain tún parapọ̀, wọ́n sì ségun àwọn Zulu ní oṣù kẹ̀je ní Ogun Ulundi, èyí sì mú ìparí bá ogun náà. Wọ́n pa agbègbè náà pọ̀ mọ́ Ìjọba Natal, ó sì padà di àra Union of South Africa.
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.