From Wikipedia, the free encyclopedia
Benito Mussolini jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Italia. Wọ́n bí Benito ní 1883. Ó kú ní ọdún 1945. Òun ni ó dá Fasisti sílẹ̀ ní Italy. Òun ni ó darí Italy ní 1922 sí 1943. Agbára ni ó fi ń darí ilẹ̀ náà (a dictator). It Duce tí ó dúró fún olórí (the leader) ni àwọn èyìn rẹ̀ máa ń pè é. Mussolini àti ìgbìmọ̀ Fascist Party ni wọn jọ ń darí Italy. Wọn kò gba alátakò kankan láyè.
Benito Mussolini | |
---|---|
40th Prime Minister of Italy | |
In office 31 October 1922 – 25 July 1943 | |
Monarch | Victor Emmanuel III |
Asíwájú | Luigi Facta |
Arọ́pò | Pietro Badoglio (Provisional Military Government) |
First Marshal of the Empire | |
In office 30 March 1938 – 25 July 1943 | |
Arọ́pò | Pietro Badoglio |
Duce of the Italian Social Republic | |
In office 23 September 1943 – 26 April 1945 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Predappio, Forlì, Italy | 29 Oṣù Keje 1883
Aláìsí | 28 April 1945 ọdún 61) Giulino di Mezzegra, Italy | (ọmọ
Ọmọorílẹ̀-èdè | Italian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Republican Fascist Party (1943-1945) National Fascist Party (1921-1943) Italian Socialist Party (1901-1914) |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Rachele Mussolini |
Profession | Politician, Journalist |
Gẹ́gẹ́ bí ajàfún-mèkúnnù (socialist) ni Mussohni ṣe wọ òṣèlú. Ó jẹ́ olóòtu ìwé-ìróyìn kan tí ó ń jẹ́ ní Avanti ṣùgbọ́n ní 1914, ó dá ìwé-ìroyìn tirẹ̀ sílẹ̀. Ó pè é ní IL Popolo d’Italia. Ní ọdún 1921 ni ó dá ẹgbẹ́ òṣèlú Fascist sile. Èrò tí ó ní nípa dídá ẹgbẹ́ òsẹ̀lú yìí sílẹ̀ ni láti lè tún Italy kọ́ kí ó sì sọ ọ́ di ìlú tí ó lágbára. Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Fascist rìn lọ sí Róòmù ní 1922 (‘Fascist March on Rome’), Ọba Victor Emmanuel III pe Mussoline láti wá gbé ìjọba tirẹ̀ kalẹ̀. Kò pẹ́ tí àwọn Fascist bẹ̀rẹ̀ síí darí ilẹ̀ Italy.
Àwọn ọmọ ogun Mussoline kọlu Ethopia ní 1905 wọ́n sì ṣẹ́gun ibẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà tí ó gbóná. Kò pé tí Mussolini ní kí àwọn ọmọ ogun òun lọ ran General Franco lọ́wọ́ nínú ogun abẹ́lé ilẹ̀ Spain. Ní ọdún 1940, Italy bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú ogun àgbáyé kejì. Italy dúró gbá gbá gba ti Germany ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ́gun Italy. Won di ebi ifidírẹmi Italy yìí ru Mussolini. Wọ́n gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀ wọ́n sì sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n. Àwọn German gba á sílẹ̀ ó wa di olórí ìjọbá tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ kan. Ní ọdún 1945, àwọn tí ó ń jà rí i mú, wọ́n sì pa á.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.