From Wikipedia, the free encyclopedia
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èso gígùn tó ṣe é jẹ,[1][2] èyí tí àwọn igi eléso mìíràn ní genus Musa máa ń jẹ jáde.[3] Ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n máa ń dín ọ̀gẹ̀dẹ̀, wọ́n sì máa ń yà wọ́n sọ́tọ̀ sí èyí tó wà fún jíjẹ. Èso náà máa ń wà ní oríṣiríṣi ìwọ̀n, àwọ̀ àti ìrísí, àmọ́, ó máa ń gùn tó sì máa ń rí ṣọnṣọ, pẹ̀lú ara tó rọ̀.
Igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ igi eléwé tó tóbi jù lọ.[4] Ìsàlẹ̀ igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń pè ní "corm".[5] Igi náà máa ń ga, tó sì máa ń dúró nílẹ̀ dáadáa. Kò sí orí ilẹ̀ tí ọ̀gẹ̀dẹ̀ ò ti lè hù, ní bí i 60 centimetres (2.0 ft) sínú ilẹ̀, ó sì fẹ̀ dáadáa.[6] Igi ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èyí tó máa ń tètè hù nínú gbogbo àwọn igi eléso yòókù. Ìwọ̀n ìdàgbàsókè ojoojúmọ́ rẹ̀ jẹ́1.4 square metres (15 sq ft) to 1.6 square metres (17 sq ft).[7][8]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.