ÌGBÉYÀWÓ ÌṢẸ̀ǸBÁYÉ ni wọ́n ń pè ní "Igba Ukwu" ní ilẹ̀ Ìgbò. Ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, ìgbéyàwó kìí ṣe ìsopọ̀ láàárín ọ̀dọ́bìnrin àti ọ̀dọ́mọkùnrin tó fẹ́ di ọkọ àti aya níkan ṣùgbọ́n ojúṣe àwọn òbí, àwọn ẹbí àti àwọn ará àdúgbò. Ìdí nìyí tí ìkọ̀sílẹ̀ fi ṣọ̀wọ́n láàárín wọn.[1]lẹ́yìn tí ọkùnrin bá ti rí obìnrin tí yóò fi ṣe aya, ohun àkọ́kọ́ tí yóò ṣe ni pé kí ó fi tó àwọn òbí rẹ̀ létí. Ètò mọ̀mí-n-mọ̀-ẹ́ ní oríṣìíríṣìí ìgbésẹ̀ nínú ìgbéyàwó Ìgbò.[2]

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́

Nínú ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yìí ni ọkùnrin tí yóò fẹ́ ìyàwó yóò ti lọ yọjú sí bàbá ìyàwó tàbí ẹbí rè (ìyàwó) kan, baba rẹ̀ ni yóò sìn-ín lọ. Ní àkókò fífi ojú gán-án-ní baba ìyàwó yìí, tí ó sábà máa ń wáyé ní ìrọ̀lẹ́, bàbá ọkọ yóò sọ ìdí tí wọ́n fi wá rí wọn. Àwọn òbí ìyàwó yóò gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní fún wọn ní ìdáhùn pàtó sí ohun tí wọ́n bá wà.[3]

Ìgbésẹ̀ kejì

Àwọn Ìtọ́kasí

Wikiwand in your browser!

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.

Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.