Indonésíà
From Wikipedia, the free encyclopedia
Indonésíà (pípè /ˌɪndoʊˈniːziə/ tàbí /ˌɪndəˈniːʒə/), lóníbiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Indonésíà (Àdàkọ:Lang-id), jẹ́ orílẹ̀-èdè ní Gúúsùìlàorùn Ásíà àti Oseania. Indonesia ní àwọn erékùṣù 17,508. Pẹ̀lú olùgbé bíi 230 ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn, òhun ni orílẹ̀-èdè olólùgbéjùlọ kẹrin láyé, ó sì ní olùgbé àwọn Mùsùlùmí tótóbijùlọ láyé. Indonésíà jẹ́ orílẹ̀-èdè olómìnira, pẹ̀lú aṣòfin àti ààrẹ adìbòyàn. Olúìlú rẹ̀ ni Jakarta. Ó ní bodè ilẹ̀ mọ́ Papua New Guinea, East Timor, àti Malaysia. Àwọn orílẹ̀-èdè míràn ìtòsí rẹ̀ náà tún ni Singapore, Philippines, Australia, àti ilẹ̀agbègbè Índíà Andaman and Nicobar Islands. Indonesia jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ olùdásílẹ̀ ASEAN àti ọmọ egbẹ́ Àwọn òkòwò únlá G-20.
|
Òṣùṣùerékùṣù Indonesia ti jẹ́ agbègbè òwò pàtàkì láti ọ̀rúndún keje, nígbàtí Srivijaya àti Majapahit ṣòwò pẹ̀lú Ṣáínà àti India. Díẹ̀díè àwọn olórí ibẹ̀ gba àpẹrẹ àṣà, ẹ̀sìn àti olóṣèlú láti òkèrè láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rúndún CE, bẹ́ẹ̀sìni àwọn ilẹ̀ọba Hindu àti Buddhisti gbòòrò. Itan Indonesia ti gba ipa latodo awon alagbara okere ti won wa sibe nitori awon ohun alumoni toni. Awon musulumi onisowo mu esin Islam wa sibe, beesini awon alagbara lati Europe ba ara won ja lati se adase owo ni awon Erekusu Spice Maluku lasiko Igba Iwari. Leyin awon orundun meta ati abo iseamusin awon ara Hollandi, Indonesia gba ilominira re leyin Ogun Agbaye 2k. Loni Indonesia je orile-ede olominira aare oniparapo to ni awon igberiko meta le logbon.
Kakiri awon opo erekusu re, Indonesia ni awon eya eniyan, ede ati esin otooto. Awon ara Java ni eya eniyan totobijulo, to si unbori loloselu. Indonesia ti sedagbasoke idamo kanna to ni ede orile-ede, orisi eya-eniyan, iseopo esin larin ogunlogo olugbe musulumi, ati itan iseamuin ati bi won se koju re.Motto orile-ede Indonesia, "Bhinneka Tunggal Ika" ("Okan ninu Opo"), tokasi awon opo orisirisi to da orile-ede yi. Botilejepe o ni olugbe pupo ati awon agbegbe sisupo ololugbe, Indonesia ni awon agbegbe aginju to ni opoelemin giga keji lagbaye. Botilejepe o ni awon ohun alumoni ile pupo aini unba ja gidigidi loni.[5]