![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/3/38/Children_play_round_game.jpg/640px-Children_play_round_game.jpg&w=640&q=50)
Ere idaraya
From Wikipedia, the free encyclopedia
Eré ìdárayá jẹ́ àṣà àti ọ̀nà ìdárayá jákè-jádò ilẹ̀ Yorùbá nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀. Yorùbá bọ̀, wọ́n ní "ohun gbogbo ni ìgbà àti àkókó ń bẹ fún". Ìran Yorùbá fẹ́ràn iṣẹ́ ṣíṣe lọ́pọ̀lọpọ̀. Wọ́n sì gbàgbọ́ wí pé iṣẹ́ ni òògùn ìṣẹ́. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti fẹràn iṣẹ́ tó, ó ní àwọn àkókò tí wọ́n máa ń fi sílẹ̀ fún eré ṣíṣe nínú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Irú àkókò bẹ́ẹ̀ ni a mọ̀ sí àkókò eré ìdárayá. Èyí fi hàn pé kì í ṣe àwọn òyìnbó ni ó mú eré ìdárayá dé ilẹ̀ Yorùbá. Yorùbá ka eré ìdárayá sí eré pàtàkì nítorí ó yé wọn pé ipa tí ó gbópọn ni eré ìdárayá ń kó nínú àlàáfíà ara àti ẹ̀mí gígùn. Bí eré ìdárayá ṣe wà fún àwọn ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ìrìnsẹ̀ náà ni ó wà fún ọmọdé àti àgbàlagbà. Bí eré abẹ́lé ti wà náà ni èyí tí à ń ṣe ní ìta wà. Oríṣìíríṣìí ni eré ìdárayá tí a máa ń ṣe nílẹ̀ Yorùbá, púpọ̀ sì ni kò mú agbára dání nítorí lẹ́yìn iṣẹ́ oòjọ́ wọ́n ni Yorùbá ń ṣe wọ́n. Wọ́n wà láti fún ara ní ìsinmi lẹ́yìn iṣẹ́ oòjọ́. Àwọn eré ìdárayá kan wà fún ìlera, láti mú kí ara làágùn. Àwọn mìíràn wà fún ìnajú, àwọn kan wà gẹ́gẹ́ bíi amúṣẹ́yá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìsọ̀rí mìíràn wà fún dídá ọ̀pọ̀lọpọ̀ lárayá. Lára eré ìdárayá Yorùbá ni eré ayò, àrin, òkòtò, ìjàkadì, kànnàkànnà, eré òṣùpá, eré àlọ́, adéndélé, kí-ní-ń-lẹ́jẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/3/38/Children_play_round_game.jpg/640px-Children_play_round_game.jpg)