Ìrìnkánkán àwọn Ẹ̀tọ́ Aráàlú ọmọ Áfríkà Amẹ́ríkà (1955–1968)
From Wikipedia, the free encyclopedia
Àdàkọ:African American topics sidebar
Àyọkà yìí únfẹ́ ìyílédèdà sí Yorùbá. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ ṣàtúnṣe sí ìyílédèdà |
Ìrìnkánkán àwọn Ẹ̀tọ́ Aráàlú ọmọ Áfríkà Amẹ́ríkà (1955–1968) (African-American Civil Rights Movement (1955–1968)) le tọ́ka sí àwọn ìrìnkánkán àwùjọ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó fẹ́ fi òfin de ìwà ẹlẹ́yàmẹ́yà sí àwọn adúláwọ̀ ará Amẹ́ríkà kí ó sì dá ẹ̀tọ́ ìdìbò padà fún wọn. Àyọkà yìí dálé apá ìrìnkánkán tó wáyé láàrin ọdún 1955 àti 1968, àgàgà ní Gúúsù. Ìjádewá ìrìnkánkan Black Power, tó bẹ̀rẹ̀ láti 1966 dé 1975, jẹ́ kí àwọn ìfojúsùn Ìrìnkánkán àwọn Ẹ̀tọ́ Aráàlú ó fẹ̀ si látí ṣàkọ́mọ́ iyì ẹ̀yà, ìtọ́ ará-ẹni olókòwò àti olóṣèlú, àti òmìnira lọ́wọ́ ìṣẹ̀gà àwọn aláwọ̀funfun ará Amẹ́ríkà.
Ìrìnkánkán náà jẹ́ dídámọ̀ pẹ̀lú ìwọ́de nínlá ìkọ̀yà aráàlú. Láàrin 1955 àti 1968, ìwọ́de aláìníjàgídíjàgan àti àìgbọràn aráàlú fa rògbòdìyàn láàrin àwọn alákitiyan àti àwọn aláṣe ìjọba. Àwọn ìjọba àpapọ̀, ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀, àwọn ilé ìṣòwò, àti àwùjọ jẹ́ pípọndandan láti kojú àwọn ìwọ́de wọ̀nyí tí wọ́n tọ́kasí àwọn àìbánidọ́gba tó únkojú àwọn ọmọ Áfríkà Amẹ́ríkà. Àwọn irú ìfarakọ̀ àti/tábí àìgbọràn aráàlú ní bọikọ́tì bíi ti Bọikọ́tì Ọkọ̀-akérò Montgomery (1955–1956) tó yọrí sí rere ní Alabama; "ìjókòódè" bíi ti ìjọ́kòó Greensboro (1960) ni North Carolina; ìwọ́de, bíi ti àwọn ìwọ́de láti Selma lọ sí Montgomery (1965) ni Alabama; àti orísirísi ọ̀pọ̀ akitiyan aláìníjàgídíjàgan.
Àyọrí aṣòfin tó wáyé nígbà Ìrìnkánkán àwọn Ẹ̀tọ́ Aráàlú yí ni ìṣọdòfin Ìṣe Òfin àwọn Ẹ̀tọ́ Aráàlú 1964,[1] tó fòfin de ìṣojúsáájú nítorí "ẹ̀yà, àwọ̀, ẹ̀sìn, tàbí orílẹ̀-èdè" ní ẹnu ìṣẹ́ àti ní ilé ìgboro; Ìṣe Òfin àwọn Ẹ̀tọ́ Ìdìbò 1965, tó ṣèdápadà àti ìdáàbòbò àwọn ẹ̀tọ́ ìdìbò; Ìṣe Òfin Ìkórawọ̀lú àti Ìjẹ́ọmọọrílẹ̀-èdè 1965, tó sí ọ̀nà ìwọlé sí Amẹ́ríkà fún àwọn ará orílè-èdè yíokù lẹ́yín àwọn tí wọ́n wá láti Europe; àti Ìṣe Òfin Ilé Ẹlẹ́tọ̀ọ́ 1968, tó fòfin de ìṣojúsáájú nínú títà tàbí yíyá ilé. Àwọn ọmọ Áfríkà Amẹ́ríkà padà sí ọ̀ṣèlú nú gúúsù, bẹ́ẹ̀sìni ní káàkiri orílẹ̀-èdè àwọn ọ̀dọ́ ní ìwúrí láti ṣàtúnṣe.