Ìrèké, jẹ́ igi tẹ́rẹ́ gíga tí ó ma dùn mìnsìn-mìnsìn nígbà tí a bá ge sẹ́nu. Ó sábà ma ń hù jùlọ níbi tí ilẹ̀ omi rẹ̀ bá wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, òun sì ni wọ́n fi ń ṣe ṣúgà jíjẹ.
Ìrísí rẹ̀
Ìrèké ma ń ga níwọ̀nn bàtà mẹ́fà sí ogún, ó.ma ń ní kókó ní ìpelel ìpele, tí adùn rẹ̀ sì ma ń dá lórí ìpele kọ̀ọ̀kan láti ìdí. Ìrèké tún jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí àgbàdo, ìrẹsì, ọkà bàbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀gbìn ìrèké lágbàáyé
Ìrèké ni ohun ọ̀gbìn tí wọ́n gbìn jùlọ ní àgbáyé pẹ̀lú iye 1.8 bílíọ́nù tọ́ọ̀nù ní ọdún 2017, nígbà tí orílẹ̀-èdè Brazil kó ìdá ogójì nínú ìpèsè ọ̀gbìn ìrèké lọ́dún náà. Ẹ̀yà ìrèké tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ (Saccharum officinarum) tí iye rẹ̀ tó ìdá àádọ́rin ni wọ́n fi ń pèsè ṣúgà jùlọ.[1][2]
Àwọn Ìtọ́ka sí
Wikiwand in your browser!
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.