![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/6/66/Social_distancing_queueing_for_the_supermarket_J._Sainsbury%2527s_north_London_Coronavirus_Covid_19_pandemic_-_30_March_2020.jpg/640px-Social_distancing_queueing_for_the_supermarket_J._Sainsbury%2527s_north_London_Coronavirus_Covid_19_pandemic_-_30_March_2020.jpg&w=640&q=50)
Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ
From Wikipedia, the free encyclopedia
Nínú ètò ìlera àwùjọ, Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ (Ìjìnnà-síra-ẹni lójúkojú),[1][2][3] jẹ́ ìlànà tí kìí ṣe nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìlò oògùn pẹ̀lú èròǹgbà láti dènà títànká àjàkálẹ̀ ààrùn nípa jíjìnnà sí ara ẹni lójúkojú láti ṣe àdínkù iye ìgbà tí àwọn ènìyàn lè súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí.[1][4] Ó jẹ mọ́ ìṣèdiwọ̀n bí ènìyàn kan ṣe lè jìnnà sí ẹlòmíràn (irú òdiwọ̀n bẹ́ẹ̀ máa ń yàtọ̀ láti ìgbà dé ìgbà àti ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan) àti yíyẹra fún ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn.[5][6]
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/6/66/Social_distancing_queueing_for_the_supermarket_J._Sainsbury%27s_north_London_Coronavirus_Covid_19_pandemic_-_30_March_2020.jpg/640px-Social_distancing_queueing_for_the_supermarket_J._Sainsbury%27s_north_London_Coronavirus_Covid_19_pandemic_-_30_March_2020.jpg)
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/4/45/Covid-19-Transmission-graphic-01.gif/640px-Covid-19-Transmission-graphic-01.gif)
Nípa Ìjìnnà-síra-ẹni, ó ṣe é ṣe kí àdínkù wà fún kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn rán ẹni tí kò láàrùn èyí tí ó lè wáyé nípa dídára pọ̀ mọ́ ẹni tí ó ti kó ààrùn, tí èyí yóò sìn ṣe àdínkù iye ẹni tí ààrùn bẹ́ẹ̀ lè pa.[1] A máa ń lo ìlànà yìí pẹ̀lú ìwà ìmọ́tótó èémí àti fífọwọ́ ẹni.[7][8] Nígbà rògbòdìyàn àjàkálẹ̀ ààrùn ẹ̀rànkòrónà 2019, àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) dábàá láti ṣègbè fún Ìjìnnà-síra-ẹni tí ó tako Ìjìnnà-sáwùjọ-eni, láti ṣàlàyé pé Ìjìnnà-síra-ẹni ni ó lè ṣe àdínkù kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn náà, àwọn ènìyàn ṣì lè ní ìbáṣepọ̀ tó dára nípa lílo ìmọ̀-ẹ̀rọ.[1][2][9][10] Láti ṣe àdínkù ìkóràn àjàkálẹ̀ ààrùn àti láti dènà iṣẹ́ àṣekúdórógbó fún àwọn elétò ìlera, pàápàá jù lọ nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin Ìjìnnà-sápèéjọ ni wọ́n là kalẹ̀, lára wọn ni títi ilé-ìwé àti àwọn ilé ìjọsìn pa, ìdágbé, ìséra-ẹni dènà àjàkálẹ̀ ààrùn, òfin kónílégbélé àti gbígbégidínà ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.[4][11]
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé sẹ́ńtúrí kọkànlélógún yìí ni ọ̀rọ̀ náà jẹyọ,[12] lílọ Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ tí wà láti láti nǹkan sẹ́ńtúrí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ náà jẹyọ nínú Bíbélì, nínú ìwé Léfítíkù, orí kẹtàlá, ẹsẹ kẹrìndínláàádọ́ta, "Adẹ́tẹ̀ náà tí ó ń ṣàìsàn ni ... yóò máa níkàn dá gbé lẹ́yìn níbi ọ̀tọ̀, ibi ọ̀tọ̀ yìí ni yóò sìn máa gbé."[13] Nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn àwọn ará Jọsitiníàn lọ́dún 541 sí 542, olórí àwọn Jọsitiníàn àkọ́kọ́ ṣọ̀fin ìyanisọ́tọ̀ dènà àjàkálẹ̀ ààrùn ní abẹ́ àṣẹ ìjọba Byzantine, lára àwọn òfin ìyanisọ́tọ̀ dènà àjàkálẹ̀ ààrùn náà ni júju òkú sínú òkun, ó sọ ní àìmọye ìgbà pé àwọn ará Júù, Samáríà, àwọn abọrìṣà, àwọn elékèé, ìwà abo kó máa bá abo sùn tàbí kí akọ máa bá akọ sùn pẹ̀lú àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn ló fa àjàkálẹ̀ ààrùn nígbà náà".[14] Láyé òde òní, lílọ Ìjìnnà-síra-ẹni dènà àjàkálẹ̀ ààrùn wáyé láti dènà onírúurú àjàkálẹ̀ ààrùn. Nígbà St. Louis, ní kété lẹ́yìn ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn, influenza sẹ́yọ láàárín ìlú lọ́dún 1918, àwọn aláṣẹ pàṣẹ títi àwọn ilé-ìwé pa, gbígbégi Dínà ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn àti aáyán Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ mìíràn. Iye àwọn ènìyàn tó kú ní St. Louis nígbà náà kò pọ̀ tó ti Philadelphia, tí wọn kò ṣàmúlò Ìjìnnà-síra-ẹni nígbà ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn influenza, àfi lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí àjàkálẹ̀ ààrùn náà bẹ́ sílẹ̀.[15] Bẹ́ẹ̀ náà, àwọn aláṣẹ tí dámọ̀ràn Ìjìnnà-síra-ẹni nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn ẹrankòrónà 2019.
Àgbékalẹ̀ Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ máa ń dènà rírànkálẹ̀ àwọn àjàkálẹ̀ ààrùn ní àwọn ìlànà wọ̀nyí:[16]
- Ikọ́ wúwú àti sísín sì ara ẹlòmíràn droplet contact
- ìfarakanra tààrà pẹ̀lú ẹlòmíràn (àti ní ìgbà ìbálòpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin)
- ìfarakanra lọ́nà ẹ̀bùrù, (fún àpẹẹrẹ fífarakan nǹkan tí ó ti ní kòkòrò ààrùn lára)
- kíkó ààrùn náà nínú atẹ́gùn, pàápàá jù lọ fún kòkòrò-àìfojúrí gbé nínú afẹ́fẹ́ fún ìgbà pípẹ́.
Àwọn ìlànà ìdènà àjàkálẹ̀ ààrùn wọ̀nyí lè máa ṣiṣẹ́ tó ti irú àjàkálẹ̀ ààrùn náà bá jẹ́ èyí tí ènìyàn lè kó nípa jíjẹ oúnjẹ tàbí omi tí ààrùn tí kóbá, tàbí nípa ẹranko agbárùnrìn bíi ẹ̀fọn, tàbí àwọn kòkòrò mìíràn.[17]
Lára awọn ìṣòro Ìjìnnà-síra-ẹni nì wọ̀nyí, ìdánìkàngbé, ìdí kù iṣẹ́ àti ṣíṣe àwọn nǹkan èlò àti pípàdánù àwọn àǹfààní tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ láwùjọ ẹni.[18]